27 Bélú 2023
Ilé ẹjọ́ ti ní kí Soun Ogbomoso, Oba Ghandi Afolabi Olaoye ṣì máa wà lórí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba títí tí ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn fi máa gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀.
Ìdájọ́ yìí lọ ń wáyé lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Oyo tó fi ìlú Ogbomoso ṣe ibùjókòó dájọ́ pé Ọba Ghandi kò yẹ lórí ipò gẹ́gẹ́ bí Soun Ogbomoso nítorí àwọn kùdìẹ̀kudiẹ kan tó wáyé lórí ìyànsípò rẹ̀.
Ní ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ́n oṣù Kẹwàá ni ilé ẹjọ́ gíga Ogbomoso náà dá Ọmọọba Kabir Laoye, tó pẹjọ́ tako Oba Ghandi pé àwọn afọbajẹ kò tẹ̀lé ìlànà tó yẹ lórí ìyànsípò rẹ̀.
Èyí ló mú ọba Ghandi gba ilé ẹjọ́ lọ láti lọ pe ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn pé ìdájọ́ náà tako ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ ti ṣáájú gbé kalẹ̀ lọ́jọ́ Kẹta oṣù Kẹwàá pé ìyànsípò òun tẹ̀lé gbogbo ìlànà tó tọ́.
Ọba Ghandi tún pé ẹjọ́ pé kí ilé ẹjọ́ gba òun láàyè láti máa jẹ́ ọba lọ ní ìlú Ogbomoso títí tí ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn fi máa dá ẹjọ́ àwọn.
Bákan náà ni ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo tó buwọ́lu ìyànsípò Oba Ghandi náà pé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn, pé kí ilé ẹjọ́ yí ìdájọ́ náà padà.
Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kọkànlá, ọdún 2023, Adájọ́ Kareem Adeyimika Adedokun ní kí Ọba Ghandi máa ṣèjọba lọ títí tí àwọn máa fi gbọ́ ẹjọ́ lórí ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó pè.
Àmọ́ ìgbẹ́jọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà kò ì tíì bẹ̀rẹ̀ títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ.
Pẹ̀lú ìdájọ́, ó ṣeéṣe kí Oba Ghandi padà sí Ogbomoso láìpẹ́ ọjọ́ láti ìrìnàjò rẹ̀ lọ sí òkè òkun látàrí àtúnṣe ààfin Soun tó ń lọ́wọ́.
Ẹ ó rántí pé ní ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023 ni àwọn afọbajẹ ìlú Ogbomoso fi Ọba Ghandi jẹ lẹ́yìn tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo buwọ́lu ìyànsípò rẹ̀.
ncG1vNJzZmivp6x7o67CZ5qopV%2BuvLPBwZpmmqqknrCtsdJomrKwYpm5uH7Xr7Co